loading

GBIGBE NINU OGO ( House Fellowship Manual Yoruba)

Ipade ojule kii se ipade ijosin miiran; bee si ni kii se ipade eko Bibeli tabi ile eko ojo isinmi miiran. O je egbe kekere lara ijo ti o wa fun sisunmo ati ajosepo fun idapo tooto. Nitori idi eyi, a ti seto iwe naa lona ti gbogbo eniyan ti o wa ni ipade naa yoo fi kopa nibe. Akiyesi: Adari ipade ojule gbodo koko se alaye ranpe lori koko eko fun ojo kookan. Gbogbo awon ti o wa ni ipade ni o gbodo gbiyanju lati dahun awon ibeere fun agbeyewo eko, ki won si ko idahun won sile (iba dara bi won ba le se akosile re sinu iwe fun idanilekoo yii) Ki gbogbo awon ti o wa ni ipade wa inu iwe mimo papo(fun awon ese Bibeli ti a toka si) lati wa idahun si awon ibeere fun agbeyewo eko. Ninu eko kookan, atona ti wa nibe. Sibe, bi o tile je pe ona ti a oo lo le yato lati ojule kan si omiran, sugbon ohun ti eko kookan wa fun gbodo fi idi mule. Oludari ipade ojule gbodo pese awon eniyan ipade sile fun eko ti o n bo, ki o rii pe gbogbo eniyan ni o n kopa nibe. Ipade igbaradi gbodo maa wa fun awon oluko lati igba de igba, o le je loseese, pelu aladari gbogbogboo fun ipade ojule. Gbogbo isoro ti a ba n dojuko ni a oo se atojo re, ki a si ko won fun alakoso idanileko kristiani fun iranlowo ti o ye nipase alabojuto ipade ojule.